Saamu 113
Psalms 113 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹ máa yin Olúwa.
Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa. 2Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 3Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn. 4Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run. 5Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
tí ó gbé ní ibi gíga. 6Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé! 7Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,
àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá. 8Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀. 9Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹ yin Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.