Saamu 112
Psalms 112 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀. 2Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún. 3Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
òdodo rẹ̀ sì dúró láé. 4Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo. 5Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
a sì wínni;
ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀. 6Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé. 7Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. 8Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. 9Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú,
nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. 10Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.