Jeremiah 50:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.
Jeremiah 50:14 in English
Jeremiah 50:14 · Berean Standard Bible
Line up in formation around Babylon, all you who draw the bow! Shoot at her! Spare no arrows! For she has sinned against the LORD.
Context
12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ
yóò sì gba ìtìjú.
Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá. 13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;
ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.
Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò
fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀. 14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli
àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà.
Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa. 15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà!
Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,
gbẹ̀san lára rẹ̀.
Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. 16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli,
àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè!
Nítorí idà àwọn aninilára
jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,
kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.