Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli, àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè! Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

Jeremiah 50:16 in English

Jeremiah 50:16 · Berean Standard Bible

Cut off the sower from Babylon, and the one who wields the sickle at harvest time. In the face of the oppressor’s sword, each will turn to his own people, each will flee to his own land.

Context

14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa. 15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. 16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli, àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè! Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀. 17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.” 18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.