Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

Jeremiah 50:15 in English

Jeremiah 50:15 · Berean Standard Bible

Raise a war cry against her on every side! She has thrown up her hands in surrender; her towers have fallen; her walls are torn down. Since this is the vengeance of the LORD, take out your vengeance upon her; as she has done, do the same to her.

Context

13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀. 14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa. 15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. 16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli, àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè! Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀. 17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.