Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

Jeremiah 50:13 in English

Jeremiah 50:13 · Berean Standard Bible

Because of the wrath of the LORD, she will not be inhabited; she will become completely desolate. All who pass through Babylon will be horrified and will hiss at all her wounds.

Context

11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù, ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin. 12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá. 13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀. 14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà. Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa. 15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.