Jeremiah 50:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.
Jeremiah 50:12 in English
Jeremiah 50:12 · Berean Standard Bible
your mother will be greatly ashamed; she who bore you will be disgraced. Behold, she will be the least of the nations, a wilderness, a dry land, and a desert.
Context
10A ó dààmú Babeli,
gbogbo àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú ìfẹ́ wọn ṣẹ,”
ni Olúwa wí. 11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,
ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn
fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù,
ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin. 12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ
yóò sì gba ìtìjú.
Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá. 13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;
ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.
Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò
fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀. 14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli
àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà.
Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.