Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.”

Jeremiah 50:17 in English

Jeremiah 50:17 · Berean Standard Bible

Israel is a scattered flock, chased away by lions. The first to devour him was the king of Assyria; the last to crush his bones was Nebuchadnezzar king of Babylon.”

Context

15Kígbe mọ́ ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn. 16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli, àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè! Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀. 17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.” 18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria. 19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.