Jeremiah 50:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.
Jeremiah 50:19 in English
Jeremiah 50:19 · Berean Standard Bible
I will return Israel to his pasture, and he will graze on Carmel and Bashan; his soul will be satisfied on the hills of Ephraim and Gilead.
Context
17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,
kìnnìún sì ti lé e lọ.
Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,
àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli
fa egungun rẹ̀ ya.” 18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí,
“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria. 19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli
padà wá pápá oko tútù rẹ̀
òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,
a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè
Efraimu àti ní Gileadi. 20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”
ni Olúwa wí,
“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,
ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;
àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan
nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí. 21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn
tí ó ń gbé ní Pekodi.
Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,”
ni Olúwa wí,
“Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.