Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

Jeremiah 50:20 in English

Jeremiah 50:20 · Berean Standard Bible

In those days and at that time, declares the LORD, a search will be made for Israel’s guilt, but there will be none, and for Judah’s sins, but they will not be found; for I will forgive the remnant I preserve.

Context

18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria. 19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi. 20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí. 21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ. 22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.