Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.

Jeremiah 50:22 in English

Jeremiah 50:22 · Berean Standard Bible

“The noise of battle is in the land— the noise of great destruction.

Context

20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun; àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí. 21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn tí ó ń gbé ní Pekodi. Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,” ni Olúwa wí, “Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ. 22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá. 23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè. 24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.