Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.

Jeremiah 50:24 in English

Jeremiah 50:24 · Berean Standard Bible

I laid a snare for you, O Babylon, and you were caught before you knew it. You were found and captured because you challenged the LORD.

Context

22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá. 23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó, lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé! Báwo ní Babeli ti di ahoro ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè. 24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Babeli, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa. 25Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli. 26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo, sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà, kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.