Jeremiah 50:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
Jeremiah 50:25 in English
Jeremiah 50:25 · Berean Standard Bible
The LORD has opened His armory and brought out His weapons of wrath, for this is the work of the Lord GOD of Hosts in the land of the Chaldeans.
Context
23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó,
lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé!
Báwo ní Babeli ti di ahoro
ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè. 24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀
fún ọ ìwọ Babeli,
kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,
o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa. 25Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde,
nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun
ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli. 26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo,
sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀,
ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà,
kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun,
ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un. 27Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ,
jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!
Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,
àkókò ìbẹ̀wò wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.