Isaiah 27:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
Isaiah 27:6 in English
Isaiah 27:6 · Berean Standard Bible
In the days to come, Jacob will take root. Israel will bud and blossom and fill the whole world with fruit.
Context
4Inú kò bí mi.
Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!
Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun,
Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn. 5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” 6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé. 7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú
gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?
Ǹjẹ́ a ti pa á
gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á? 8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó
fi dojúkọ ọ́
pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.