Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”

Isaiah 27:5 in English

Isaiah 27:5 · Berean Standard Bible

Or let them lay claim to My protection; let them make peace with Me— yes, let them make peace with Me.”

Context

3Èmi Olúwa ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára. 4Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun, Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn. 5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” 6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé. 7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.