Isaiah 27:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
Isaiah 27:7 in English
Isaiah 27:7 · Berean Standard Bible
Has the LORD struck Israel as He struck her oppressors? Was she killed like those who slayed her?
Context
5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” 6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé. 7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú
gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?
Ǹjẹ́ a ti pa á
gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á? 8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó
fi dojúkọ ọ́
pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́. 9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà
fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,
èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti
ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ
dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,
kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí
tí yóò wà ní ìdúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.