Isaiah 27:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.
Isaiah 27:9 in English
Isaiah 27:9 · Berean Standard Bible
Therefore Jacob’s guilt will be atoned for, and the full fruit of the removal of his sin will be this:* When he makes all the altar stones like crushed bits of chalk, no Asherah poles or incense altars will remain standing.
Context
7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú
gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?
Ǹjẹ́ a ti pa á
gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á? 8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó
fi dojúkọ ọ́
pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,
gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́. 9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà
fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,
èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti
ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ
dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,
kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí
tí yóò wà ní ìdúró. 10Ìlú olódi náà ti dahoro,
ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì
gẹ́gẹ́ bí aginjù;
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko
níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;
wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán. 11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù
àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná
nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́,
nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.