Isaiah 27:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́, nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.
Isaiah 27:11 in English
Isaiah 27:11 · Berean Standard Bible
When its limbs are dry, they are broken off. Women come and use them for kindling; for this is a people without understanding. Therefore their Maker has no compassion on them, and their Creator shows them no favor.
Context
9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà
fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,
èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti
ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ
dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,
kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí
tí yóò wà ní ìdúró. 10Ìlú olódi náà ti dahoro,
ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì
gẹ́gẹ́ bí aginjù;
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko
níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;
wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán. 11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù
àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná
nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́,
nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n. 12Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 13Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.