Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Isaiah 27:12 in English

Isaiah 27:12 · Berean Standard Bible

In that day the LORD will thresh from the flowing Euphrates * to the Wadi of Egypt, and you, O Israelites, will be gathered one by one.

Context

10Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán. 11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́, nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n. 12Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 13Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.