Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.

Isaiah 27:8 in English

Isaiah 27:8 · Berean Standard Bible

By warfare and exile * You contended with her and removed her with a fierce wind, as on the day the east wind blows.

Context

6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé. 7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á? 8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́. 9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró. 10Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.