Isaiah 27:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun, Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
Isaiah 27:4 in English
Isaiah 27:4 · Berean Standard Bible
I am not angry. If only thorns and briers confronted Me, I would march and trample them, I would burn them to the ground.
Context
2Ní ọjọ́ náà,
“Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan. 3Èmi Olúwa ń bojútó o,
Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.
Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru
kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára. 4Inú kò bí mi.
Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!
Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun,
Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn. 5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” 6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.