Native Bible

Ezekiel 32:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga, àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ.

Ezekiel 32:6 in English

Ezekiel 32:6 · Berean Standard Bible

I will drench the land with the flow of your blood, all the way to the mountains— the ravines will be filled.

Context

4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba. Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ní orí rẹ. Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ. 5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí àwọn òkè gíga ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún àwọn àárín àwọn òkè gíga. 6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga, àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ. 7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn; èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. 8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ; èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.