Esekiẹli 32:7
Ezekiel 32:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn; èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
Ezekiel 32:7 in English
Ezekiel 32:7 · Berean Standard Bible
When I extinguish you, I will cover the heavens and darken their stars. I will cover the sun with a cloud, and the moon will not give its light.
Context
5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
àwọn àárín àwọn òkè gíga. 6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ. 7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. 8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
kò í tí ì mọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.