Esekiẹli 32:5
Ezekiel 32:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí àwọn òkè gíga ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún àwọn àárín àwọn òkè gíga.
Ezekiel 32:5 in English
Ezekiel 32:5 · Berean Standard Bible
I will put your flesh on the mountains and fill the valleys with your remains.*
Context
3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn
èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́
wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi. 4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀
èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.
Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe
àtìpó ní orí rẹ.
Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi
ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ. 5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
àwọn àárín àwọn òkè gíga. 6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ. 7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.