Native Bible

Ezekiel 32:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.

Ezekiel 32:3 in English

Ezekiel 32:3 · Berean Standard Bible

This is what the Lord GOD says: ‘I will spread My net over you with a company of many peoples, and they will draw you up in My net.

Context

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un: “ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà; ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀. 3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi. 4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba. Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ní orí rẹ. Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ. 5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí àwọn òkè gíga ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún àwọn àárín àwọn òkè gíga.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.