Native Bible

Ezekiel 32:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un: “ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà; ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.

Ezekiel 32:2 in English

Ezekiel 32:2 · Berean Standard Bible

“Son of man, take up a lament for Pharaoh king of Egypt and say to him: ‘You are like a lion among the nations; you are like a monster in the seas. You thrash about in your rivers, churning up the waters with your feet and muddying the streams.’

Context

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un: “ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà; ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀. 3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi. 4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba. Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ní orí rẹ. Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.