Esekiẹli 32:4
Ezekiel 32:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀ èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba. Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ní orí rẹ. Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ.
Ezekiel 32:4 in English
Ezekiel 32:4 · Berean Standard Bible
I will abandon you on the land and hurl you into the open field. I will cause all the birds of the air to settle upon you, and all the beasts of the earth to eat their fill of you.
Context
2“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un:
“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà;
ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun
to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ,
ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi
láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀. 3“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn
èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́
wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi. 4Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀
èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.
Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe
àtìpó ní orí rẹ.
Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi
ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ. 5Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
àwọn àárín àwọn òkè gíga. 6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.