Native Bible

Ezekiel 32:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ; èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.

Ezekiel 32:8 in English

Ezekiel 32:8 · Berean Standard Bible

All the shining lights in the heavens I will darken over you, and I will bring darkness upon your land,’ declares the Lord GOD.

Context

6Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga, àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ. 7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn; èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. 8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ; èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀. 10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn. Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.