Native Bible

Ezekiel 32:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn. Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

Ezekiel 32:10 in English

Ezekiel 32:10 · Berean Standard Bible

I will cause many peoples to be appalled over you, and their kings will shudder in horror because of you when I brandish My sword before them. On the day of your downfall each of them will tremble every moment for his life.’

Context

8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ; èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀. 10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́, àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn. Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ. 11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Idà ọba Babeli yóò wá sí orí rẹ, 12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ. Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká, gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.