Esekiẹli 32:11
Ezekiel 32:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Idà ọba Babeli yóò wá sí orí rẹ,
Ezekiel 32:11 in English
Ezekiel 32:11 · Berean Standard Bible
For this is what the Lord GOD says: ‘The sword of the king of Babylon will come against you!
Context
9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
kò í tí ì mọ̀. 10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn.
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ. 11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Idà ọba Babeli
yóò wá sí orí rẹ, 12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀. 13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.