Sekariah 13:7
Zechariah 13:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké.
Zechariah 13:7 in English
Zechariah 13:7 · Berean Standard Bible
Awake, O sword, against My Shepherd, against the man who is My Companion, declares the LORD of Hosts. Strike the Shepherd, and the sheep will be scattered,* and I will turn My hand against the little ones.
Context
5Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’ 7“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké. 8Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀. 9Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,
èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,
èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:
wọn yóò sì pé orúkọ mi,
èmi yóò sì dá wọn lóhùn:
èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’
àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.