Sekariah 13:6
Zechariah 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’
Zechariah 13:6 in English
Zechariah 13:6 · Berean Standard Bible
If someone asks him, ‘What are these wounds on your chest *?’ he will answer, ‘These are the wounds I received in the house of my friends.’
Context
4“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’ 7“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké. 8Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.