Sekariah 13:8
Zechariah 13:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí, “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú; ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
Zechariah 13:8 in English
Zechariah 13:8 · Berean Standard Bible
And in all the land, declares the LORD, two-thirds will be cut off and perish, but a third will be left in it.
Context
6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’ 7“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké. 8Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀. 9Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,
èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,
èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:
wọn yóò sì pé orúkọ mi,
èmi yóò sì dá wọn lóhùn:
èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’
àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.