Native Bible

Zechariah 13:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”

Zechariah 13:9 in English

Zechariah 13:9 · Berean Standard Bible

This third I will bring through the fire; I will refine them like silver and test them like gold. They will call on My name, and I will answer them. I will say, ‘They are My people,’ and they will say, ‘The LORD is our God.’”

Context

7“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké. 8Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí, “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú; ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀. 9Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.