Sekariah 13:5
Zechariah 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’
Zechariah 13:5 in English
Zechariah 13:5 · Berean Standard Bible
He will say, ‘I am not a prophet; I work the land, for I was purchased as a servant in my youth.*’
Context
3Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè, nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀. 4“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’ 7“Dìde, ìwọ idà, sí Olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèké.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.