Sekariah 13:4
Zechariah 13:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.
Zechariah 13:4 in English
Zechariah 13:4 · Berean Standard Bible
And on that day every prophet who prophesies will be ashamed of his vision, and he will not put on a hairy cloak in order to deceive.
Context
2“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́, àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. 3Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè, nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀. 4“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.