Orin Solomoni 1:6
Song of Songs 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(4) Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́! (5) Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni. (6) Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú, nítorí oòrùn mú mi dúdú, ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
Song of Songs 1:6 in English
Song of Songs 1:6 · Berean Standard Bible
(4) It is only right that they adore you. (5) I am dark, yet lovely, O daughters of Jerusalem, like the tents of Kedar, like the curtains of Solomon. (6) Do not stare because I am dark, for the sun has gazed upon me. My mother’s sons were angry with me; they made me a keeper of the vineyards, but my own vineyard I have neglected.
Context
4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. 5(4) Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. 6(4) Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
(5) Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
(6) Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú. 7Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. 8Bí ìwọ kò bá mọ̀,
ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.