Orin Solomoni 1:5
Song of Songs 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(4) Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.
Song of Songs 1:5 in English
Song of Songs 1:5 · Berean Standard Bible
(4) We will rejoice and delight in you; we will praise your love more than wine.
Context
3Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ. 4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. 5(4) Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. 6(4) Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
(5) Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
(6) Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú. 7Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.