Orin Solomoni 1:4
Song of Songs 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.
Song of Songs 1:4 in English
Song of Songs 1:4 · Berean Standard Bible
Take me away with you—let us hurry! May the king bring me to his chambers.
Context
2Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ. 3Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.
Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde
abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ. 4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá
ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. 5(4) Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;
a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. 6(4) Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
(5) Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
(6) Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.