Native Bible

Song of Songs 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.

Song of Songs 1:2 in English

Song of Songs 1:2 · Berean Standard Bible

Let him kiss me with the kisses of his mouth! For your love is more delightful than wine.

Context

1Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni. 2Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ. 3Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ. 4Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.