Orin Solomoni 1:8
Song of Songs 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ìwọ kò bá mọ̀, ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ, kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
Song of Songs 1:8 in English
Song of Songs 1:8 · Berean Standard Bible
If you do not know, O fairest of women, follow the tracks of the flock, and graze your young goats near the tents of the shepherds.
Context
6(4) Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
(5) Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu
dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,
bí aṣọ títa ti Solomoni.
(6) Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,
nítorí oòrùn mú mi dúdú,
ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi
ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;
ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú. 7Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,
níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.
Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,
kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán
ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. 8Bí ìwọ kò bá mọ̀,
ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.
Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,
kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.
Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn. 9Olùfẹ́ mi,
mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao. 10Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,
ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.