Saamu 38:13
Psalms 38:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
Psalms 38:13 in English
Psalms 38:13 · Berean Standard Bible
But like a deaf man, I do not hear; and like a mute man, I do not open my mouth.
Context
11Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè. 12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́. 13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀. 14Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn. 15Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.