Native Bible

Psalms 38:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.

Psalms 38:11 in English

Psalms 38:11 · Berean Standard Bible

My beloved and friends shun my disease, and my kinsmen stand at a distance.

Context

9Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ. 10Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi. 11Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè. 12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́. 13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.