Native Bible

Psalms 38:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

Psalms 38:12 in English

Psalms 38:12 · Berean Standard Bible

Those who seek my life lay snares; those who wish me harm speak destruction, plotting deceit all day long.

Context

10Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi. 11Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè. 12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́. 13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀. 14Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.