Native Bible

Psalms 38:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

Psalms 38:14 in English

Psalms 38:14 · Berean Standard Bible

I am like a man who cannot hear, whose mouth offers no reply.

Context

12Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́. 13Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀. 14Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn. 15Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè; ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn. 16Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí; nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.