Native Bible

Psalms 108:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.

Psalms 108:3 in English

Psalms 108:3 · Berean Standard Bible

I will praise You, O LORD, among the nations; I will sing Your praises among the peoples.

Context

1Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin. 2Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù, 3èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn. 4Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀. 5Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.