Native Bible

Psalms 108:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

Psalms 108:5 in English

Psalms 108:5 · Berean Standard Bible

Be exalted, O God, above the heavens; may Your glory cover all the earth.

Context

3èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn. 4Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀. 5Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé. 6Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn 7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.