Native Bible

Numbers 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)

Numbers 13:16 in English

Numbers 13:16 · Berean Standard Bible

These were the names of the men Moses sent to spy out the land; and Moses gave to Hoshea son of Nun the name Joshua.

Context

14láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi; 15láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki. 16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.) 17Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè. 18Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.