Native Bible

Numbers 13:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.

Numbers 13:18 in English

Numbers 13:18 · Berean Standard Bible

See what the land is like and whether its people are strong or weak, few or many.

Context

16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.) 17Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè. 18Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.