Native Bible

Numbers 13:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè.

Numbers 13:17 in English

Numbers 13:17 · Berean Standard Bible

When Moses sent them to spy out the land of Canaan, he told them, “Go up through the Negev and into the hill country.

Context

15láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki. 16Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.) 17Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè. 18Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.